Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:12 - Yoruba Bible

12 Àwọn Juu mẹta kan tí ń jẹ́ Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, tí o fi ṣe alákòóso àwọn agbègbè ní ìjọba Babiloni tàpá sí àṣẹ ọba, wọn kò sin ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:12
15 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ.


Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ, ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?


Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.


Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.


Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.


Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.


ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó.


Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí.


“Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.”


Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni.


Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”


Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀.


Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!”


“Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan