Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:1 - Yoruba Bible

1 Nebukadinesari fi kìkì wúrà yá ère kan tí ó ga ní ọgọta igbọnwọ (mita 27), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹfa (mita 2.7). Ó gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè Babiloni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NEBUKADNESSARI ọba, si yá ere wura kan, eyi ti giga rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa: o si gbé e kalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, ni igberiko Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:1
29 Iomraidhean Croise  

Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.”


Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia.


Wúrà ati fadaka ni àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fi ṣe oriṣa wọn, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.


Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn.


Mose bá pada tọ OLUWA lọ, ó ní, “Yéè! Àwọn eniyan wọnyi ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá; wọ́n ti fi wúrà yá ère fún ara wọn;


Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù, ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ. Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.


Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”


Àwọn kan ń kó ọpọlọpọ wúrà jáde ninu àpò, wọ́n sì ń wọn fadaka lórí ìwọ̀n. Wọ́n sanwó ọ̀yà fún alágbẹ̀dẹ wúrà, ó bá wọn fi dá oriṣa. Wọ́n wá ń foríbalẹ̀ fún un, wọ́n ń sìn ín.


Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi, ati wúrà láti ìlú Ufasi. Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n, ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà. Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupa ati ti elése àlùkò, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn.


Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun? Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.”


Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.


Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.


Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?


Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni.


Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.


Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta.


Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali.


“Wọ́n ń fi ọba jẹ, láìsí àṣẹ mi. Wọ́n ń yan àwọn aláṣẹ, ṣugbọn n kò mọ̀ nípa rẹ̀. Wọ́n ń fi fadaka ati wúrà wọn yá ère fún ìparun ara wọn.


Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá.


Nígbà tí a jẹ́ ọmọ Ọlọrun, kò yẹ kí á rò pé Ọlọrun dàbí ère wúrà, tabi fadaka, tabi òkúta, ère tí oníṣẹ́ ọnà ṣe pẹlu ọgbọ́n ati èrò eniyan.


Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa!


Sísun ni kí ẹ sun gbogbo àwọn ère oriṣa wọn; ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò wúrà tabi fadaka tí ó wà lára wọn. Ẹ kò gbọdọ̀ kó wọn fún ara yín, kí wọn má baà di ohun ìkọsẹ̀ fun yín, nítorí ohun ìríra ni wọ́n lójú OLUWA Ọlọrun yín.


Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan