Daniẹli 2:9 - Yoruba Bible9 Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.” Faic an caibideilBibeli Mimọ9 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” Faic an caibideil |
“Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ati gbogbo eniyan ni wọ́n mọ̀ pé bí ẹnikẹ́ni bá lọ sọ́dọ̀ ọba ninu yàrá inú lọ́hùn-ún, láìṣe pé ọba pè é, òfin kan tí ọba ní fún irú eniyan bẹ́ẹ̀ ni pé kí á pa á, àfi bí ọba bá na ọ̀pá wúrà tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni náà ni wọn kò fi ní pa á. Ṣugbọn ó ti tó ọgbọ̀n ọjọ́ sẹ́yìn tí ọba ti pè mí.”