Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:5 - Yoruba Bible

5 Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi: tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:5
10 Iomraidhean Croise  

Wọ́n wó àwọn ère ati ilé ìsìn Baali lulẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ di ilé ìgbẹ́ títí di òní yìí.


Siwaju sí i, mo tún pàṣẹ pé, bí ẹnikẹ́ni bá rú òfin mi yìí, kí wọ́n yọ ọ̀kan ninu igi òrùlé rẹ̀; kí wọ́n gbẹ́ ẹ ṣóńṣó, kí wọ́n tì í bọ̀ ọ́ láti ìdí títí dé orí rẹ̀. Kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ààtàn.


“Nítorí náà, ẹ fi èyí lékàn, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọrun, kí n má baà fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbà yín kalẹ̀.


Jẹ́ kí wọ́n rá, kí wọn ṣàn lọ bí omi; kí á tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bíi koríko, kí wọn sì rọ.


Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.


“Nítorí náà, mo pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, tabi orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati ti Abedinego, fífà ni a ó fa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ya ní tapá-titan, a ó sì sọ ilé rẹ̀ di ahoro; nítorí kò sí ọlọrun mìíràn tí ó lè gbani là bẹ́ẹ̀.”


Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.


Ẹ kó gbogbo ìkógun tí ẹ bá rí ninu ìlú náà jọ sí ààrin ìgboro rẹ̀, kí ẹ sì dáná sun gbogbo rẹ̀ bí ẹbọ sísun sí OLUWA Ọlọrun yín. Ìlú náà yóo di àlàpà títí lae, ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ tún un kọ́ mọ́.


Joṣua bá gégùn-ún nígbà náà pé, “Ẹni ìfibú OLUWA ni ẹnikẹ́ni tí ó bá dìde láti tún ìlú Jẹriko kọ́. Àkọ́bí ẹni tí ó bá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ yóo kú, àbíkẹ́yìn rẹ̀ yóo kú nígbà tí ó bá gbé ìlẹ̀kùn ibodè rẹ̀ ró.”


Samuẹli bá sọ fún un pé, “Bí idà rẹ ti sọ ọpọlọpọ ìyá di aláìlọ́mọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyá tìrẹ náà yóo di aláìlọ́mọ láàrin àwọn obinrin.” Samuẹli bá gé Agagi wẹ́lẹwẹ̀lẹ níwájú pẹpẹ ní Giligali.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan