Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:41 - Yoruba Bible

41 Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Ati gẹgẹ bi iwọ ti ri ẹsẹ ati ọmọkasẹ ti o jẹ apakan amọ̀ amọkoko, ati apakan irin, ni ijọba na yio yà si ara rẹ̀; ṣugbọn ipá ti irin yio wà ninu rẹ̀, niwọn bi iwọ ti ri irin ti o dapọ mọ amọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:41
8 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú.


Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára.


Àwọn ìwo mẹ́wàá dúró fún àwọn ọba mẹ́wàá, tí yóo jáde lára ìjọba kẹrin yìí. Ọ̀kan yóo jáde lẹ́yìn wọn, tí yóo yàtọ̀ sí wọn, yóo sì borí mẹta ninu àwọn ọba náà.


“Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní.


Mo wá tún rí àmì mìíràn ní ọ̀run: Ẹranko Ewèlè ńlá kan tí ó pupa bí iná, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá, ó dé adé meje.


Mo wá rí ẹranko kan tí ń ti inú òkun jáde bọ̀. Ó ní ìwo mẹ́wàá ati orí meje. Adé mẹ́wàá wà lórí ìwo rẹ̀. Ó kọ orúkọ àfojúdi sára orí rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.


“Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan