Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:22 - Yoruba Bible

22 Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:22
37 Iomraidhean Croise  

Josẹfu dá Farao lóhùn, ó ní, “Kò sí ní ìkáwọ́ mi, Ọlọrun ni yóo fún kabiyesi ní ìdáhùn rere.”


Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀, ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri.


Kedere ni isà òkú rí níwájú Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni ìparun kò farasin.


Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ, ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.


Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn wọ́n.


Nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà; ninu ìmọ́lẹ̀ rẹ ni a ti ń rí ìmọ́lẹ̀.


Ta ló dàbí ọlọ́gbọ́n? Ta ló sì mọ ìtumọ̀ nǹkan? Ọgbọ́n ní ń mú kí ojú ọlọ́gbọ́n máa dán, á mú kí ó tújúká kí ó gbàgbé ìṣòro.


Ẹ mú wọn wá, kí ẹ sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fún wa; kí ẹ sọ àwọn ohun àtijọ́ fún wa. Kí á lè gbé wọn yẹ̀wò; kí á lè mọ àyọrísí wọn, tabi kí ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ fún wa.”


Ta ló kéde rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, kí á lè mọ̀, ta ló sọ nípa rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ kí á lè sọ pé, ‘Olóòótọ́ ni?’ Kò sí ẹni tí ó sọ ọ́, kò sí ẹni tí ó kéde rẹ̀; ẹnìkankan kò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Wò ó! Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá, àwọn nǹkan tuntun ni mò ń kéde nisinsinyii. Kí wọn tó yọjú jáde rárá, ni mo ti sọ fún ọ nípa wọn.”


Èmi ni mo dá ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn, èmi ni mo dá alaafia ati àjálù: Èmi ni OLUWA tí mo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi.


Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?


“Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.”


Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”


Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo.


Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”


Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;


Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́.


Ìdí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nìyí, nítorí wọ́n lajú sílẹ̀ ni, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọ́n ní etí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn.


Èyí ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tí ó wá sinu ayé, tí ó ń tàn sí gbogbo aráyé.


Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.


Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”


Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


tí Ọlọrun kò fihan àwọn ọmọ eniyan ní ìgbà àtijọ́, ṣugbọn tí ó fihan àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ ati àwọn wolii rẹ̀ nisinsinyii, ninu ẹ̀mí.


OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’


òun nìkan tí kì í kú, tí ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí eniyan kò lè súnmọ́, tí ẹnikẹ́ni kò rí rí, tí eniyan kò tilẹ̀ lè rí. Tirẹ̀ ni ọlá ati agbára tí kò lópin. Amin.


Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.


Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.


Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan