Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:21 - Yoruba Bible

21 Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:21
40 Iomraidhean Croise  

Gbogbo aráyé a sì máa fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, láti tẹ́tí sí ọgbọ́n tí Ọlọrun fún un.


Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ irú ìdájọ́ tí Solomoni ọba dá yìí, ó mú kí ó túbọ̀ níyì lójú wọn; nítorí wọ́n mọ̀ pé Ọlọrun ni ó fún un ní ọgbọ́n láti ṣe ìdájọ́ ní irú ọ̀nà ẹ̀tọ́ bẹ́ẹ̀.


Ọgbọ́n ati òye tí Ọlọrun fún Solomoni kọjá sísọ, ìmọ̀ rẹ̀ sì kọjá ìwọ̀n.


Kí OLUWA fún ọ ní ọgbọ́n ati làákàyè kí o lè máa pa òfin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́ nígbà tí ó bá fi ọ́ jọba lórí Israẹli.


Àkọsílẹ̀ yìí sọ bí ó ti ṣe ìjọba rẹ̀, bí agbára rẹ̀ ti tó; ati gbogbo nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí i, ati èyí tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israẹli ati sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká wọn.


Ọba bá fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n ní òye nípa àkókò, (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ọba máa ń ṣe sí gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òfin ati ìdájọ́.


Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀, ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí.


Mo sì ti fi ẹ̀mí Ọlọrun kún inú rẹ̀, mo ti fún un ní òye ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ iṣẹ́ ọnà,


Mo ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani pẹlu rẹ̀. Mo sì ti fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà ní ọgbọ́n, kí wọ́n lè ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ.


Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá.


Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli.


Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.


Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé, ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára.


Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi, ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún, nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára, o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí, nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.”


Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”


ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀.


Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’


“Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.


a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”


Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀.


nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.


Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n.


Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè.


Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.


Bí ẹnikẹ́ni bá wà ninu yín, tí ọgbọ́n kù díẹ̀ kí ó tó fún, kí olúwarẹ̀ bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun, yóo sì fún un. Nítorí Ọlọrun lawọ́, kì í sìí sìrègún.


A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan