Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:13 - Yoruba Bible

13 Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Nigbana ni aṣẹ jade lọ pe, ki nwọn ki o pa awọn amoye; nwọn si nwá Danieli pẹlu awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lati pa wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:13
8 Iomraidhean Croise  

Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ, àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?


Àwọn tí ń ṣe òfin tí kò tọ́ gbé! Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn akọ̀wé, tí ń kọ̀wé láti ni eniyan lára;


Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan