Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:12 - Yoruba Bible

12 Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Babeli run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:12
14 Iomraidhean Croise  

Dájúdájú ibinu a máa pa òmùgọ̀, owú jíjẹ a sì máa pa aláìmọ̀kan.


Dájúdájú ibinu eniyan yóo pada di ìyìn fún ọ; àwọn tí wọ́n bá sì bọ́ lọ́wọ́ ibinu rẹ yóo ṣe àjọ̀dún rẹ.


Iranṣẹ ikú ni ibinu ọba, ọlọ́gbọ́n eniyan níí tù ú lójú.


Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù.


Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ẹni tí ó bá mú ọba bínú fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu.


Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀, onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.


Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”


Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.


Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba.


Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


Nígbà tí Hẹrọdu rí i pé àwọn amòye tan òun jẹ ni, inú bí i pupọ. Ó bá pàṣẹ pé kí wọn máa pa gbogbo àwọn ọmọ-ọwọ́ lọkunrin ní Bẹtilẹhẹmu ati ní gbogbo agbègbè ibẹ̀ láti ọmọ ọdún meji wálẹ̀ títí di ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, gẹ́gẹ́ bí àkókò tí ó fọgbọ́n wádìí lọ́wọ́ àwọn amòye.


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan