Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:11 - Yoruba Bible

11 Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:11
25 Iomraidhean Croise  

Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ.


Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un.


“Ṣugbọn, ǹjẹ́ ìwọ Ọlọrun lè gbé inú ayé yìí? Nítorí pé bí gbogbo ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́; kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ?


“Ṣugbọn ṣé ìwọ Ọlọrun yóo máa bá eniyan gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bí ọ̀run ti tóbi tó, kò gbà ọ́, mélòó mélòó ni ilé tí mo kọ́ yìí?


Ó ní, “Ìhín ni ibi ìsinmi mi títí lae, níhìn-ín ni n óo máa gbé, nítorí pé ó wù mí.


Ó gun òkè gíga, ó kó àwọn eniyan nígbèkùn; ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan, ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá. OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.


N óo máa wà láàrin àwọn eniyan Israẹli, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.


Àwọn pidánpidán náà sọ fún Farao pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí.” Ṣugbọn ọkàn Farao le, kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀.


Múra sí àfọ̀ṣẹ rẹ, sì múra si oṣó ṣíṣẹ́ jọ, tí o ti dáwọ́ lé láti kékeré, bóyá o óo tilẹ̀ yege, tabi bóyá o sì lè dẹ́rùba eniyan.


Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.


Ẹ wò ó! Èmi ati àwọn ọmọ tí OLUWA fún mi, a wà fún àmì ati ìyanu ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun, tí ń gbé orí òkè Sioni.


“Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi.


Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;


N óo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn tí ẹ pa, n kò sì ní dá ẹlẹ́bi sí, nítorí èmi OLUWA ni mò ń gbé Sioni.”


Ẹ má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé di aláìmọ́, àní, ilẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli láàrin àwọn tí èmi OLUWA ń gbé.”


Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”


Ọ̀rọ̀ náà wá di eniyan, ó ń gbé ààrin wa, a rí ògo rẹ̀, ògo bíi ti Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí ó ti ọ̀dọ̀ Baba wá, tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́.


Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.


Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé.


Kí ni oriṣa ń wá ninu ilé Ọlọrun? Nítorí ilé Ọlọrun alààyè ni àwa jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ, pé, “N óo máa gbé ààrin wọn, n óo máa káàkiri ní ààrin wọn. N óo jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì jẹ́ eniyan mi.


Mo wá gbọ́ ohùn líle kan láti orí ìtẹ́ náà wá tí ó wí pé, “Ọlọrun pàgọ́ sí ààrin àwọn eniyan, yóo máa bá wọn gbé, wọn yóo jẹ́ eniyan rẹ̀, Ọlọrun pàápàá yóo wà pẹlu wọn;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan