Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:10 - Yoruba Bible

10 Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:10
5 Iomraidhean Croise  

Ọpọlọpọ ìmọ̀ràn tí wọn fún ọ ti sú ọ; jẹ́ kí wọn dìde nílẹ̀ kí wọ́n gbà ọ́ wàyí, àwọn tí ó ń wojú ọ̀run, ati àwọn awòràwọ̀; tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí ọ, nígbà tí oṣù bá ti lé.


Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.


Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un.


Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní,


Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan