Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:7 - Yoruba Bible

7 Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:7
30 Iomraidhean Croise  

“Mo fi Ọlọrun tí ó gba ẹ̀tọ́ mi búra, mo fi Olodumare tí ó mú kí ọkàn mi bàjẹ́ ṣẹ̀rí,


A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”, “Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”. Wọn óo máa pè yín ní, “Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”; wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní, “Ìlú tí a kò patì”.


tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”


Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn.


Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú.


“Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà.


Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”


Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”


Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ,


Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé. “Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀ láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀, àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀.


“Bí mo ti ń wò ó, mo rí i ti ìwo yìí ń bá àwọn eniyan mímọ́ jà, tí ó sì ń ṣẹgun wọn,


Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀.


Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ náà dáhùn pé, “Nǹkan wọnyi yóo máa rí báyìí lọ títí fún ẹgbaa ó lé ọọdunrun (2,300) ọdún, lẹ́yìn náà a óo ya ibi mímọ́ sí mímọ́.”


Agbára rẹ̀ yóo pọ̀, ṣugbọn kò ní jẹ́ nípa ipá rẹ̀, yóo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí ó bá ń ṣe, yóo sì mú kí á run àwọn eniyan Ọlọrun ati àwọn alágbára.


Nítorí náà, ẹ má ronú tẹ́lẹ̀ ohun tí ẹ óo sọ láti dáàbò bo ara yín,


Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé.


Ó ní òun óo gbé ọ ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí ó dá lọ. O óo níyì jù wọ́n lọ; o óo ní òkìkí jù wọ́n lọ, o óo sì lọ́lá jù wọ́n lọ. O óo jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí.”


Nítorí pé, OLUWA yóo dá àwọn eniyan rẹ̀ láre, yóo sì ṣàánú fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, nígbà tí ó bá rí i pé wọn kò lágbára mọ́, ati pé kò sí olùrànlọ́wọ́ fún wọn, tí kò sì ṣẹ́ku ẹnìkan ninu wọn, kì báà ṣe ẹrú tabi òmìnira.


Níwọ̀n bí mo ṣe jẹ́ Ọlọrun alààyè, mo fi ara mi búra.


Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun.


Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.


Ni a bá fún obinrin náà ní ìyẹ́ idì ńláńlá meji, kí ó lè fò lọ sí aṣálẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀ fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ó fi bọ́ lọ́wọ́ ejò náà.


Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260).


A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji.


àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé,


Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà bá fi ògo, ọlá ati ìyìn fún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan