Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:5 - Yoruba Bible

5 Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nigbana ni emi Danieli wò, si kiyesi i, awọn meji miran si duro: ọ̀kan lapa ihín eti odò, ati ekeji lapa ọhún eti odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:5
5 Iomraidhean Croise  

Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù.


Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.


Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”


Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan