Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:2 - Yoruba Bible

2 Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:2
19 Iomraidhean Croise  

À máa ń yin eniyan gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe gbọ́n tó, ṣugbọn ọlọ́kàn àgàbàgebè yóo di ẹni ẹ̀gàn.


Àwọn òkú wa yóo jí, wọn óo dìde kúrò ninu ibojì. Ẹ tají kí ẹ máa kọrin, ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀. Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín, ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.


Wọn óo jáde, wọn óo sì fojú rí òkú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí mi; nítorí ìdin tí ń jẹ wọ́n kò ní kú, bẹ́ẹ̀ ni iná tí ń jó wọn kò ní kú; wọn óo sì jẹ́ ohun ìríra lójú gbogbo eniyan.”


Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu mi bíi jagunjagun tí ó bani lẹ́rù. Nítorí náà àwọn tí wọn ń lépa mi yóo kọsẹ̀, apá wọn kò ní ká mi. Ojú yóo tì wọ́n lọpọlọpọ nítorí wọn kò ní lè borí mi. Ẹ̀sín tí ẹnikẹ́ni kò ní gbàgbé yóo dé bá wọn títí lae.


Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí o wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘N óo ṣí ibojì yín; n óo sì gbe yín dìde, ẹ̀yin eniyan mi, n óo mu yín pada sí ilé, ní ilẹ̀ Israẹli.


N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́.


Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”


Mo sì ń wojú Ọlọrun nítorí pé mo ní ìrètí kan náà tí àwọn ará ibí yìí pàápàá tí wọn ń rojọ́ mi ní, pé gbogbo òkú ni yóo jinde, ati ẹni rere ati ẹni burúkú.


Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú.


Àbí amọ̀kòkò kò ní ẹ̀tọ́ láti ṣe amọ̀ rẹ̀ bí ó ti wù ú bí? Bí ó bá fẹ́, ó lè fi amọ̀ rẹ̀ mọ ìkòkò tí ó wà fún èèlò ọ̀ṣọ́. Bí ó bá sì tún fẹ́, ó lè mú lára amọ̀ kan náà kí ó fi mọ ìkòkò mìíràn fún èèlò lásán.


Nítorí bí a bá gbàgbọ́ pé Jesu kú, ó sì jinde, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọrun yóo mú àwọn tí wọ́n ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀.


Mo rí òkú àwọn ọlọ́lá ati ti àwọn mẹ̀kúnnù, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà. Àwọn ìwé àkọsílẹ̀ wà ní ṣíṣí. Ìwé mìíràn tún wà ní ṣíṣí, tí orúkọ àwọn alààyè wà ninu rẹ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ àwọn òkú gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn tí ó wà ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan