Daniẹli 12:12 - Yoruba Bible12 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà. Faic an caibideilBibeli Mimọ12 Ibukún ni fun ẹniti o duro dè, ti o si de ẹgbẹrun, ati ọdurun le marundilogoji ọjọ nì. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335). Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.