Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:8 - Yoruba Bible

8 Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Yóò gba òrìṣà wọn, ère dídá àti ohun èlò oníye lórí ti fàdákà àti ti wúrà, yóò sì kó wọn lọ sí Ejibiti. Fún ọdún díẹ̀ yóò fi ọba àríwá lọ́rùn sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:8
17 Iomraidhean Croise  

Mo mọ̀ pé ọkàn rẹ fà sí ilé ni o fi sá, ṣugbọn, èéṣe tí o fi jí àwọn ère oriṣa mi kó?”


Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ.


“Nítorí pé, ní òru ọjọ́ náà ni n óo la gbogbo ilẹ̀ Ijipti kọjá, n óo pa gbogbo àkọ́bí ilẹ̀ náà, ati ti eniyan ati ti ẹranko, n óo sì jẹ gbogbo àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti níyà. Èmi ni OLUWA.


ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi, ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára.


ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run.


OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.


N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.


Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.


Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò.


Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú.


tí wọn ń sin òkú àwọn àkọ́bí wọn tí OLUWA pa, OLUWA fihàn pé òun ní agbára ju oriṣa àwọn ará Ijipti lọ.


Ẹ wó gbogbo pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ fọ́ gbogbo òpó wọn, ẹ dáná sun àwọn ère oriṣa Aṣera wọn, ẹ gé gbogbo àwọn ère oriṣa wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò níbẹ̀.


Ó bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ kó àwọn oriṣa mi, tí mo dà, ẹ mú alufaa mi lọ; kí ni ó kù mí kù. Ẹ tún wá ń bi mí pé, Kí ló ń ṣe mí?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan