Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:7 - Yoruba Bible

7 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 “Ọ̀kan lára àwọn ìdílé e rẹ̀, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò dìde láti gba ipò o rẹ̀. Yóò sì kọlu ogun ọba àríwá, yóò sì wó odi alágbára; yóò bá wọn jà yóò sì borí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:7
14 Iomraidhean Croise  

“Nítorí pé ìrètí ń bẹ fún igi tí wọn gé, yóo tún pada rúwé, ẹ̀ka rẹ̀ kò sì ní ṣe aláìsọ.


Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú, kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.


Ṣugbọn ìwọ, Ọlọrun, o óo sọ àwọn apani ati àwọn alárèékérekè, sinu kòtò ìparun; wọn kò ní lo ìdajì ọjọ́ ayé wọn. Ṣugbọn èmi óo gbẹ́kẹ̀lé ọ.


Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.


Nítorí náà, OLUWA yóo fi ìyà jẹ Israẹli. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo, yóo gé Israẹli lórí ati nírù.


O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò; wọ́n dàgbà, wọ́n so èso; orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ.


Kò ní sá àsálà, nítorí pé kò náání ìbúra ó sì da majẹmu, ati pé ó ti tọwọ́ bọ ìwé, sibẹsibẹ, ó tún ṣe gbogbo nǹkan tí ó ṣe.”


“Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò.


Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!


Ṣugbọn Ọlọrun wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè yìí! Ní alẹ́ yìí ni a óo gba ẹ̀mí rẹ pada lọ́wọ́ rẹ. Ta ni yóo wá jogún gbogbo ohun tí o kó jọ wọnyi?’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan