Daniẹli 11:6 - Yoruba Bible6 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ6 Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí. Faic an caibideil |