Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:41 - Yoruba Bible

41 Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

41 Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Edomu, Moabu àti àwọn olórí Ammoni yóò bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:41
9 Iomraidhean Croise  

“Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.”


“Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


àwọn ará Ijipti, àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Edomu, ati àwọn ọmọ Amoni àwọn ará Moabu, ati gbogbo àwọn tí ń gbé inú aṣálẹ̀; tí wọn ń fá apá kan irun orí wọn; nítorí pé bí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi kò ṣe kọlà abẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Israẹli kò kọlà ọkàn.”


Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.


Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.


Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.”


Lára ọ̀kan ninu àwọn ìwo mẹrin ọ̀hún ni ìwo kékeré kan ti yọ jáde, ó gbilẹ̀ lọ sí ìhà gúsù, sí ìhà ìlà oòrùn ati sí Ilẹ̀ Ìlérí náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan