Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:3 - Yoruba Bible

3 “Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni ọba alágbára kan yóò fi ara hàn, yóò ṣe àkóso pẹ̀lú agbára ńlá, yóò sì ṣe bí ó ti wù ú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:3
10 Iomraidhean Croise  

Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.


“Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.


Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀; a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyé ati láàrin àwọn ogun ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò, tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


“Bí mo ti ń wò mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó dàbí ẹkùn, òun náà ní ìyẹ́ mẹrin lẹ́yìn. Ó ní orí mẹrin. A sì fún un ní agbára láti jọba.


Ìjọba Giriki ni òbúkọ onírun jákujàku tí o rí. Ọba àkọ́kọ́ tí yóo jẹ níbẹ̀ ni ìwo ńlá tí ó wà láàrin ojú rẹ̀.


Nípasẹ̀ Kristi kan náà ni Ọlọrun ti pín wa ní ogún. Ètò tí ó ti ṣe fún wa nìyí, òun tí ó ń mú ohun gbogbo ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.


Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.


Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa, kí á lè jẹ́ àkọ́kọ́ ninu àwọn ẹ̀dá rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan