Daniẹli 11:18 - Yoruba Bible18 Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run. Faic an caibideilBibeli Mimọ18 Lẹhin eyi, yio kọ oju rẹ̀ si erekuṣu wọnni, yio si gbà ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn balogun kan fun ara rẹ̀, yio fi opin si ẹ̀gan rẹ̀: ati nipò eyi, yio mu ẹ̀gan rẹ̀ pada wá sori ara rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní18 Nígbà náà ni yóò yí ara padà sí ilẹ̀ etí Òkun, yóò mú ọ̀pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n aláṣẹ kan yóò mú òpin bá àfojúdi rẹ̀, yóò sì yí àfojúdi rẹ̀ padà sí orí rẹ̀. Faic an caibideil |
“N óo sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn. N óo rán àwọn tí ó yè lára wọn sí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn bíi: Taṣiṣi, Puti, ati Ludi, ilẹ̀ àwọn tafàtafà, ati Tubali ati Jafani, ati àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré; àwọn tí kò tíì gbọ́ òkìkí mi, tí wọn kò sì tíì rí ògo mi rí. Wọn óo sì ròyìn ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.