Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:10 - Yoruba Bible

10 “Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò múra ogun wọn yóò kó ogun ńlá jọ, èyí tí a ó gbá lọ bí àgbàrá omi ńlá, yóò sì gbá a lọ títí dé ìlú olódi rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:10
10 Iomraidhean Croise  

OLUWA yóo bi odi gíga rẹ̀ wó, yóo wó o palẹ̀, yóo sì sọ ọ́ di erùpẹ̀ ilẹ̀.


Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀. Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀.


Yóo tú àwọn ọmọ ogun ká níwájú rẹ̀, ati ọmọ aládé tí wọn bá dá majẹmu.


Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú.


Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.


Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.


Lẹ́yìn ọdún mejilelọgọta lọ́nà meje yìí, wọn óo pa ẹni àmì òróró Ọlọrun kan láìṣẹ̀. Àwọn ọmọ ogun alágbára kan tí yóo joyè, yóo pa Jerusalẹmu ati Tẹmpili run. Òpin óo dé bá a bí àgbàrá òjò, ogun ati ìsọdahoro tí a ti fi àṣẹ sí yóo dé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan