Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:9 - Yoruba Bible

9 Mo bá gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀, nígbà tí mo gbọ́ ohùn rẹ̀, mo dojúbolẹ̀, oorun sì gbé mi lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Sibẹ mo gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀: nigbati mo si gbọ́ ohùn ọ̀rọ rẹ̀, nigbana ni mo dãmu, mo si wà ni idojubolẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, bí mo ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí i, mo sùn lọ fọnfọn, ní ìdojúbolẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:9
11 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí oòrùn ń wọ̀ lọ, oorun bẹ̀rẹ̀ sí kun Abramu, ó sì sun àsùnwọra, jìnnìjìnnì mú un, òkùnkùn biribiri sì bò ó mọ́lẹ̀.


Nígbà náà OLUWA Ọlọrun kun ọkunrin yìí ní oorun àsùnwọra, nígbà tí ó sùn, Ọlọrun yọ ọ̀kan ninu àwọn egungun ìhà rẹ̀, ó sì fi ẹran dípò rẹ̀.


Ninu àlá, lójú ìran ní ààrin òru, nígbà tí eniyan bá sun oorun àsùnwọra, lórí ibùsùn wọn,


Ninu ìran lóru, nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,


Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn. Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn. Ṣílẹ̀kùn fún mi, arabinrin mi, olùfẹ́ mi, àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye, nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù, gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.


Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.


Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde,


Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.


Ó bá dìde lórí adura, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí wọn tí wọn ń sùn nítorí àárẹ̀ ìbànújẹ́.


Ṣugbọn oorun ti ń kun Peteru ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀. Nígbà tí wọ́n tají, wọ́n rí ògo rẹ̀ ati àwọn ọkunrin meji tí wọ́n dúró tì í.


Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan