Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:7 - Yoruba Bible

7 Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:7
8 Iomraidhean Croise  

Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”


Ẹ wọnú àpáta lọ, kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀. Ẹ sá fún ibinu OLUWA ati ògo ọlá ńlá rẹ̀.


Ǹjẹ́ ẹnìkan lè sápamọ́ sí ìkọ̀kọ̀ kan tí n kò fi ní rí i? Kì í ṣe èmi ni mo wà ní gbogbo ọ̀run tí mo sì tún wà ní gbogbo ayé?


“Ìwọ ọmọ eniyan, máa jẹun. Bí o tí ń jẹun lọ́wọ́, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ máa gbọ̀n, kí o sì máa fi ìwárìrì ati ìbẹ̀rù mu omi rẹ.


Àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi rí ìmọ́lẹ̀ náà, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ohùn ẹni tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀.


Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan.


Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan