Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:3 - Yoruba Bible

3 N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:3
11 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀.


Tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu rẹ̀ yóo kọ oúnjẹ, oúnjẹ àdídùn óo sì rùn sí i.


Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn.


Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan.


Ọba bá lọ sí ààfin rẹ̀, ó fi gbogbo òru náà gbààwẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn eléré ṣe eré níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì lè sùn.


Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀.


Ẹ kó fadaka, ẹ kó wúrà! Ìlú náà kún fún ìṣúra, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye.


Ṣugbọn nígbà tí ìwọ bá ń gbààwẹ̀, bọ́jú kí o sì fi nǹkan pa ara,


O kò fi òróró kùn mí lórí. Ṣugbọn obinrin yìí fi òróró olóòórùn dídùn kùn mí lẹ́sẹ̀.


Ṣugbọn mò ń fi ìyà jẹ ara mi, mò ń kó ara mi ní ìjánu. Ìdí ni pé nígbà tí mo bá ti waasu fún àwọn ẹlòmíràn tán, kí èmi alára má baà di ẹni tí kò ní yege ninu iré-ìje náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan