Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:16 - Yoruba Bible

16 Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:16
29 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Mose wí fún OLUWA pé, “OLUWA mi, n kò lè sọ̀rọ̀ dáradára kí o tó bá mi sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni lẹ́yìn tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ tán, nítorí pé akólòlò ni mí.”


Ṣugbọn Mose tún ní, “OLUWA mi, mo bẹ̀ ọ́, rán ẹlòmíràn.”


Nítorí pé ọpọlọpọ ọgbọ́n a máa mú ọpọlọpọ ìbànújẹ́ wá, ẹni tí ń fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ rẹ̀, ó ń fi kún ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ ni.


Ó sì fi ògúnná náà kàn mí lẹ́nu, ó ní: “Wò ó, èyí ti kàn ọ́ ní ètè: A ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu.


Mo rí kinní kan lókè awọsanma tí ó wà lórí wọn, ó dàbí ìtẹ́ tí a fi òkúta safire ṣe; mo sì rí kinní kan tí ó dàbí eniyan, ó jókòó lórí nǹkankan bí ìtẹ́ náà.


Ṣugbọn bí mo bá bá ọ sọ̀rọ̀ tán, n óo là ọ́ lóhùn, o óo sì sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun bá sọ fún wọn. Ẹni tí ó bá fẹ́, kí ó gbọ́, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó má gbọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni ìdílé wọn.”


Ẹ̀mí OLUWA ti bà lé mi ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó ṣáájú ọjọ́ tí ẹni tí ó sá àsálà náà dé, OLUWA sì ti là mí lóhùn kí ọkunrin náà tó dé ọ̀dọ̀ mi ní àárọ̀ ọjọ́ keji; n kò sì yadi mọ́.


Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”


Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.


“Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú.


“Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.”


Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan.


Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.”


Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo sùn lọ fọnfọn, mo dojúbolẹ̀. Ó bá fọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dìde,


Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi.


Bí mo ti ń gbadura, ni Geburẹli, tí mo rí lójúran ní àkọ́kọ́ bá yára fò wá sọ́dọ̀ mi, ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́.


Lẹsẹkẹsẹ ohùn Sakaraya bá là, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀, ó ń yin Ọlọrun.


nítorí èmi fúnra mi ni n óo fi ọ̀rọ̀ si yín lẹ́nu, n óo sì fun yín ní ọgbọ́n tí ó fi jẹ́ pé ẹnikẹ́ni ninu gbogbo àwọn tí ó lòdì si yín kò ní lè kò yín lójú, tabi kí wọ́n rí ohun wí si yín.


Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”


Ọkunrin náà dáhùn pé, “Rárá, mo wá gẹ́gẹ́ bíi balogun àwọn ọmọ ogun OLUWA ni.” Joṣua bá dojúbolẹ̀, ó sin OLUWA, ó sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe, OLUWA mi?”


Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà.


Manoa bá gbadura sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, jọ̀wọ́ jẹ́ kí iranṣẹ rẹ tí o rán sí wa tún pada wá, kí ó wá kọ́ wa bí a óo ṣe máa tọ́jú ọmọkunrin tí a óo bí.”


Gideoni dá a lóhùn, ó ní “Jọ̀wọ́, oluwa mi, bí OLUWA bá wà pẹlu wa, kí ló dé tí gbogbo nǹkan wọnyi fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbo sì ni gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu OLUWA wà, tí àwọn baba wa máa ń sọ fún wa nípa rẹ̀, pé, ‘Ṣebí OLUWA ni ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti?’ Ṣugbọn nisinsinyii OLUWA ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”


Gideoni dáhùn, ó ní, “Sọ fún mi OLUWA, báwo ni mo ṣe lè gba Israẹli sílẹ̀? Ìran mi ni ó rẹ̀yìn jùlọ ninu ẹ̀yà Manase, èmi ni mo sì kéré jù ní ìdílé wa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan