Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:7 - Yoruba Bible

7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:7
13 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti.


Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.


Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya.


Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin.


Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,


Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli.


Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”


Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.


Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi.


Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní:


nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan