Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:6 - Yoruba Bible

6 Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:6
10 Iomraidhean Croise  

bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


bí Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè fi òdodo wọn gbàlà.”


nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú.


Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin.


Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya,


Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.”


Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda?


Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ọkàn rẹ̀ dàrú lọpọlọpọ, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ títí ilẹ̀ fi ṣú láti gba Daniẹli sílẹ̀.


“Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ).


“Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan