Daniẹli 1:4 - Yoruba Bible4 kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea. Faic an caibideilBibeli Mimọ4 Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní4 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. Faic an caibideil |
Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.”