Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:3 - Yoruba Bible

3 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:3
6 Iomraidhean Croise  

Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni.


Ó ní, ‘Ọjọ́ ń bọ̀ tí a óo ru gbogbo ohun tí ó wà láàfin rẹ lọ sí Babiloni, ati gbogbo ìṣúra tí àwọn baba ńlá rẹ ti kó jọ títí di òní. Kò ní ku nǹkankan.’ OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.


‘A óo kó ninu àwọn ọmọ bíbí inú rẹ lọ, a óo sì fi wọ́n ṣe ìwẹ̀fà láàfin ọba Babiloni.’ ”


Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa,


Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan