Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:2 - Yoruba Bible

2 OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Oluwa si fi Jehoiakimu, ọba Juda le e lọwọ, pẹlu apakan ohun-elo ile Ọlọrun, ti o kó lọ si ilẹ Ṣinari, si ile oriṣa rẹ̀: o si kó ohun-elo na wá sinu ile-iṣura oriṣa rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:2
30 Iomraidhean Croise  

Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni.


Bí àwọn eniyan ṣe ń ṣí káàkiri ní ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní agbègbè Babiloni, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ.


Ní àkókò ìjọba Jehoiakimu ni Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti Jerusalẹmu, Jehoiakimu sì di iranṣẹ rẹ̀ fún ọdún mẹta. Lẹ́yìn náà, ó pada lẹ́yìn Nebukadinesari, ó sì ṣọ̀tẹ̀ sí i.


Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni Jehoiakimu nígbà tí ó jọba. Ó wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀.


Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó ninu àwọn ohun èlò ilé OLUWA lọ sí Babiloni, ó kó wọn sinu ààfin rẹ̀ ní Babiloni.


Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu.


Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.


Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́, ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́? Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni, ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀; tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.


Ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu, ọmọ Josaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kinni tí Nebukadinesari jọba Babiloni, Jeremaya wolii gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nípa gbogbo àwọn ará Juda.


Lẹ́yìn náà, mo bá àwọn alufaa ati gbogbo àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀, mo ní, “OLUWA sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín tí wọn ń wí fun yín pé wọn kò ní pẹ́ kó àwọn ohun èlò ilé èmi OLUWA pada wá láti Babiloni. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín.


Kí ó tó pé ọdún meji, òun óo kó gbogbo ohun èlò tẹmpili òun pada, tí Nebukadinesari ọba Babiloni kó láti ibí yìí lọ sí Babiloni.


Ṣugbọn nígbà tí Nebukadinesari, ọba Babiloni gbógun ti ilẹ̀ yìí, a wí fún ara wa pé kí á wá sí Jerusalẹmu nítorí ìbẹ̀rù àwọn ọmọ ogun, àwọn ará Kalidea ati ti àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe di ẹni tí ń gbé Jerusalẹmu.”


“Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ta àsíá, kí o sì kéde. Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé, ‘Ogun tí kó Babiloni, ojú ti oriṣa Bẹli, oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú. Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’


N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni, n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́, odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.


Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda?


“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.


Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ.


Ó dáhùn pé, “Ilẹ̀ Ṣinari ni wọ́n ń gbé e lọ, láti lọ kọ́lé fún un níbẹ̀. Tí wọ́n bá parí ilé náà, wọn yóo gbé e kalẹ̀ sibẹ.”


Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ṣe lè lé ẹgbẹrun eniyan? Àní, eniyan meji péré ṣe lè lé ẹgbaarun eniyan sá? Bí kò bá jẹ́ pé Ọlọrun aláàbò wọn ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀, tí OLUWA sì ti fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́.


Inú bí OLUWA sí àwọn ọmọ Israẹli, ó bá fi wọ́n lé àwọn jàǹdùkú ọlọ́ṣà kan lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jí wọn ní nǹkan kó. OLUWA tún fi wọ́n lé gbogbo àwọn ọ̀tá tí ó wà ní àyíká wọn lọ́wọ́, apá wọn kò sì ká àwọn ọ̀tá wọn mọ́.


Nítorí náà, inú bí OLUWA sí wọn, ó sì fi wọ́n lé Kuṣani Riṣataimu ọba Mesopotamia lọ́wọ́; wọn sì sìn ín fún ọdún mẹjọ.


OLUWA bá fi wọ́n lé Jabini ọba Kenaani, tí ó jọba ní Hasori lọ́wọ́; Sisera, tí ń gbé Haroṣeti-ha-goimu ni olórí ogun rẹ̀.


Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan