Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:18 - Yoruba Bible

18 Nígbà tí ó tó àkókò tí ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn wá, olórí ìwẹ̀fà kó gbogbo wọn wá siwaju rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Nigbati o si di opin ọjọ ti ọba ti da pe ki a mu wọn wá, nigbana ni olori awọn iwẹfa mu wọn wá siwaju Nebukadnessari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:18
4 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá.


Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin.


Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba.


Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan