Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Peteru 3:3 - Yoruba Bible

3 Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Peteru 3:3
17 Iomraidhean Croise  

“Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ óo ti pẹ́ tó ninu àìmọ̀kan yín? Àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn yóo ti ní inú dídùn pẹ́ tó ninu ẹ̀gàn pípa wọn, tí àwọn òmùgọ̀ yóo sì kórìíra ìmọ̀?


Pẹ̀gànpẹ̀gàn a máa wá ọgbọ́n, sibẹ kò ní rí i, ṣugbọn ati ní ìmọ̀ kò ṣòro fún ẹni tí ó ní òye.


A máa fi àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn ṣe ẹlẹ́yà, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.


Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan, tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.


nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán, àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo; àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun;


Tí wọn ń wí pé: “Kí ó tilẹ̀ ṣe kíá, kí ó ṣe ohun tí yóo ṣe, kí á rí i. Jẹ́ kí àbá Ẹni Mímọ́ Israẹli di òtítọ́ kí ó ṣẹlẹ̀, kí á lè mọ̀ ọ́n!”


Ní ọjọ́ tí ọba ń ṣe àjọyọ̀, àwọn ìjòyè mu ọtí àmupara, títí tí ara wọn fi gbóná; ọba pàápàá darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́yà.


Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́, ó ní ohun tí yóo dá a lẹ́jọ́, ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ ni yóo dá a lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹyìn.


A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere.


Kí o mọ èyí pé àkókò ìṣòro ni ọjọ́ ìkẹyìn yóo jẹ́.


Ní àkókò ìkẹyìn yìí, ó wá bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ẹni tí ó fi ṣe àrólé ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá ayé.


Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀.


Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ. Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run.


Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.


Àwọn wọnyi ni àwọn tí wọn ń kùn ṣá, nǹkan kì í fi ìgbà kan tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn ni wọ́n ń lépa. Ẹnu wọn gba ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà. Kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe láti rí ohun tí wọ́n fẹ́. Wọn á máa wá ojú rere àwọn tí wọ́n bá lè rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn.


Wọ́n kìlọ̀ fun yín pé ní àkókò ìkẹyìn, àwọn kan yóo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóo máa tẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn láì bẹ̀rù Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan