Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:2 - Yoruba Bible

2 nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:2
11 Iomraidhean Croise  

N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.


Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.


Èmi a máa ṣe gbogbo nǹkan wọnyi nítorí ti ìyìn rere, kí n lè ní ìpín ninu ibukun rẹ̀.


Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi.


Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.


Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà.


Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀.


Bí a bá wí pé a kò lẹ́ṣẹ̀, ara wa ni à ń tàn jẹ, òtítọ́ kò sì sí ninu wa.


Ẹ̀yin baba, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé inú yín, ẹ sì ti ṣẹgun Èṣù.


Ayé ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń kọjá lọ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóo wà títí lae.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan