Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




2 Johanu 1:1 - Yoruba Bible

1 Èmi Alàgbà ni mo kọ ìwé yìí sí àyànfẹ́ arabinrin ati àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ràn nítòótọ́. Kì í ṣe èmi nìkan ni mo fẹ́ràn rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ ni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Alàgbà, Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




2 Johanu 1:1
25 Iomraidhean Croise  

Mo ti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí ohun gbogbo fínnífínní. Èmi náà wá pinnu láti kọ ìwé sí ọ lẹ́sẹẹsẹ, ọlọ́lá jùlọ, Tiofilu,


ẹ óo mọ òtítọ́, òtítọ́ yóo sì sọ yín di òmìnira.”


Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn.


Ẹ kí Rufọsi, àṣàyàn onigbagbọ ati ìyá rẹ̀ tí ó tún jẹ́ ìyá tèmi náà.


Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”


Ṣugbọn a kò fi ìgbà kankan gbà wọ́n láyè rárá, kí ó má dàbí ẹni pé ọ̀rọ̀ tiwọn ni ó borí, kí òtítọ́ ìyìn rere lè wà pẹlu yín.


Ẹ̀yin ará Galatia, ẹ mà kúkú gọ̀ o! Ta ni ń dì yín rí? Ẹ̀yin tí a gbé Jesu Kristi tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu sí níwájú gbangba!


Ẹ ti ń sáré ìje dáradára bọ̀. Ta ni kò jẹ́ kí ẹ gba òtítọ́ mọ́?


Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín.


ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo eniyan rí ìgbàlà, tí ó sì fẹ́ kí wọn ní ìmọ̀ òtítọ́.


Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.


Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.


Nítorí náà, mo bẹ àwọn àgbà láàrin yín, alàgbà ni èmi náà, ati ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, n óo sì ní ìpín ninu ògo tí yóo farahàn.


Ìjọ tí Ọlọrun yàn, ẹlẹgbẹ́ yín tí ó wà ní Babiloni ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maku, ọmọ mi.


Kì í ṣe pé ẹ kò mọ òtítọ́ ni mo ṣe kọ ìwé si yín, ṣugbọn nítorí pé ẹ mọ̀ ọ́n ni, kò sí irọ́ kankan tí ó lè jáde láti inú òtítọ́.


Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ti ọ̀rọ̀ ẹnu tabi ti ètè lásán; ṣugbọn kí ó jẹ́ ti ìwà ati ti òtítọ́.


Àwọn ọmọ àyànfẹ́ arabinrin rẹ kí ọ.


Nisinsinyii mo bẹ̀ ọ́, arabinrin, kì í ṣe pé mò ń kọ òfin titun sí ọ, yàtọ̀ sí èyí tí a ti níláti ìbẹ̀rẹ̀, pé kí á fẹ́ràn ọmọnikeji wa.


Èmi, Alàgbà, ni mo kọ ìwé yìí sí ọ, Gaiyu olùfẹ́, ẹni tí mo fẹ́ràn nítòótọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan