Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 5:2 - Yoruba Bible

2 Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ẹ mã tọju agbo Ọlọrun ti mbẹ lãrin nyin, ẹ mã bojuto o, kì iṣe afipáṣe, bikoṣe tifẹtifẹ; bẹni ki iṣe ọrọ ère ijẹkujẹ, ṣugbọn pẹlu ọkàn ti o mura tan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 5:2
41 Iomraidhean Croise  

Àwọn alufaa náà kò tún nǹkankan ṣe ninu ilé OLUWA títí tí ó fi di ọdún kẹtalelogun tí Joaṣi ti jọba.


Ìwọ tí o lẹ́wà jùlọ láàrin àwọn obinrin, bí o kò bá mọ ibẹ̀, ṣá máa tẹ̀lé ipa agbo ẹran. Jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹran rẹ máa jẹko lẹ́bàá àgọ́ àwọn olùṣọ́-aguntan.


Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn.


Wọ̀bìà ni wọ́n, alájẹkì, wọn kì í yó. Àwọn olùdarí wọn pàápàá kò mọ nǹkankan. Gbogbo wọn ti tẹ̀ sí ọ̀nà ara wọn, olukuluku wọn ń wá èrè fún ara rẹ̀.


Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”


Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́, ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀. Wọ́n bèèrè pé, ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà? Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀, tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?


Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́, ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín. N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, omi yóo sì máa dà lójú mi, nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn.


Ẹ gbé ojú sókè, kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá. Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà, àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?


OLUWA ní, “Láti orí àwọn mẹ̀kúnnù títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ràn èrè àjẹjù; láti orí àwọn wolii títí dé orí àwọn alufaa, èké ni gbogbo wọn.


Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn, n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn. Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù, títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki, gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù. Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.


Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.


“Ẹ̀yin aguntan mi, aguntan pápá mi, ẹ̀yin ni eniyan mi; èmi sì ni Ọlọrun yín.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.


Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Àwọn ilé ìdáná níbi tí àwọn alufaa tí óo wà níbi pẹpẹ yóo ti máa se ẹran ẹbọ àwọn eniyan mi nìyí.”


Àwọn aláṣẹ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó ṣe ìdájọ́, àwọn alufaa ń gba owó iṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kọ́ni, àwọn wolii ń gba owó kí wọ́n tó ríran; sibẹsibẹ, wọ́n gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, wọ́n ń wí pé, “Ṣebí OLUWA wà pẹlu wa? Nǹkan burúkú kò ní ṣẹlẹ̀ sí wa.”


Yóo dìde, yóo sì mójútó àwọn eniyan rẹ̀ pẹlu agbára OLUWA, àní, ninu ọláńlá orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Wọn óo máa gbé ní àìléwu, nítorí yóo di ẹni ńlá jákèjádò gbogbo ayé.


OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.


Olùṣọ́-aguntan mi tí kò bá níláárí gbé! Tí ó ń fi agbo ẹran sílẹ̀. Idà ni yóo ṣá a ní apá, yóo sì bá a ní ojú ọ̀tún, apá rẹ̀ óo rọ patapata, ojú ọ̀tún rẹ̀ óo sì fọ́ patapata.”


Ìbá ti dára tó kí ẹnìkan ninu yín ti ìlẹ̀kùn tẹmpili pa, kí ẹ má baà máa wá tanná mọ́, kí ẹ máa rú ẹbọ asán lórí pẹpẹ mi! Inú mi kò dùn si yín, n kò sì ní gba ọrẹ tí ẹ mú wá.


Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”


“Ẹ má bẹ̀rù mọ́, agbo kékeré; nítorí dídùn inú Baba yín ni láti fun yín ní ìjọba rẹ̀.


Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí.


Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.”


Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà.


Ta ló jẹ́ ṣe iṣẹ́ ọmọ-ogun tí yóo tún máa bọ́ ara rẹ̀? Ta ló jẹ́ dá oko láì má jẹ ninu èso rẹ̀? Ta ló jẹ́ máa tọ́jú aguntan láìmu ninu wàrà aguntan tí ó ń tọ́jú?


Kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí, tabi ẹni tí máa ń lu eniyan. Ṣugbọn kí ó jẹ́ onífaradà. Kò gbọdọ̀ jẹ́ alásọ̀, tabi ẹni tí ó ní ọ̀kánjúwà owó.


Bákan náà ni kí àwọn diakoni jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́. Kí wọn má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu meji. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó ń mutí para. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ oníwọ̀ra eniyan.


Dandan ni kí o pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí pé wọ́n ń da odidi agbo-ilé rú, wọ́n sì ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ tí kò tọ́ nítorí èrè tí kò yẹ.


Nítorí alabojuto ìjọ níláti jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọrun. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí yóo máa ṣe ti inú ara rẹ̀, tabi kí ó jẹ́ onínúfùfù. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn ìjà, tabi ẹni tí ó ní ìwọ̀ra nípa ọ̀rọ̀ owó.


ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.


Máa rán wọn létí kí wọn máa tẹríba fún ìjọba ati àwọn aláṣẹ, kí wọn máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu, kí wọn sì múra láti máa ṣe iṣẹ́ rere gbogbo.


Ṣugbọn n kò fẹ́ dá nǹkankan ṣe láìjẹ́ pé o lọ́wọ́ sí i, n kò fẹ́ kí ó jẹ́ pé túlààsì ni oore tí mo fẹ́ kí o ṣe. Inú rẹ ni mo fẹ́ kí ó ti wá.


Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.


Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan