Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 4:1 - Yoruba Bible

1 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Kristi ti jìyà ninu ara, kí ẹ̀yin náà di ọkàn yín ní àmùrè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹni tí ó bá jìyà nípa ti ara ti bọ́ lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NJẸ bi Kristi ti jìya fun wa nipa ti ara, irú inu kanna ni ki ẹnyin fi hamọra: nitori ẹniti o ba ti jìya nipa ti ara, o ti bọ́ lọwọ ẹ̀ṣẹ;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 4:1
17 Iomraidhean Croise  

Ẹ wẹ̀, kí ara yín dá ṣáká. Ẹ má hùwà burúkú níwájú mi mọ́. Ẹ má ṣe iṣẹ́ ibi mọ́.


Wọn óo dáná sun àwọn ilé rẹ, wọn óo sì ṣe ìdájọ́ fún ọ lójú àwọn obinrin pupọ. N kò ní jẹ́ kí o ṣe àgbèrè mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní jẹ́ kí o fún àwọn olólùfẹ́ rẹ ní ẹ̀bùn mọ́.


Ó wí fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde dúró ní ààrin àwùjọ.”


Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi.


Kí á má rí i. Báwo ni àwa tí a ti fi ayé ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, ṣe tún lè máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀?


Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.


Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi.


Àwọn tíí ṣe ti Kristi Jesu ti kan àwọn nǹkan ti ara mọ́ agbelebu pẹlu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ati ìgbádùn ara.


Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró.


Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.”


Ẹ máa ní èrò yìí ninu ara yín, irú èyí tí ó wà ninu Kristi Jesu,


Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀.


Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.


Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan