Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:9 - Yoruba Bible

9 Ẹ má fi burúkú gbẹ̀san burúkú, tabi kí ẹ fi àbùkù kan ẹni tí ó bá fi àbùkù kàn yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ wọn ní rere ni. Irú ìwà tí a ní kí ẹ máa hù nìyí, kí ẹ lè jogún ibukun tí Ọlọrun ṣèlérí fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ẹ máṣe fi buburu san buburu, tabi fi ẽbú san ẽbú; ṣugbọn kàka bẹ̃, ẹ mã súre; nitori eyi li a pè nyin si, ki ẹnyin ki o le jogún ibukún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:9
26 Iomraidhean Croise  

Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí.


Ẹni tí ó fibi san oore, ibi kò ní kúrò ninu ilé rẹ̀ lae.


Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú, gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.


Ẹni tí ó ṣi olódodo lọ́nà lọ sinu ibi, yóo já sinu kòtò tí òun fúnrarẹ̀ gbẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn aláìlẹ́bi eniyan yóo jogún ire.


Gbogbo ẹni tí ó bá sì fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, baba tabi ìyá, ọmọ tabi ilẹ̀ sílẹ̀, nítorí orúkọ mi, yóo gba ìlọ́po-ìlọ́po ní ọ̀nà ọgọrun-un, yóo sì tún jogún ìyè ainipẹkun.


Nígbà náà ni ọba yóo sọ fún àwọn ti ọwọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bukun. Ẹ wá jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fun yín kí á tó dá ayé.


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹ má ṣe gbẹ̀san bí ẹnikẹ́ni bá ṣe yín níbi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹnìkan bá gbá yín létí ọ̀tún, ẹ kọ ti òsì sí i.


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín.


Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń ṣe inúnibíni yín, kàkà kí ẹ ṣépè, ìre ni kí ẹ máa sú fún wọn.


Ẹ má máa fi burúkú san burúkú. Ẹ jẹ́ kí èrò ọkàn yín sí gbogbo eniyan máa jẹ́ rere.


Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé.


Àwọn tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwọn ni ó pè. Àwọn tí ó pè ni ó dá láre. Àwọn tí ó sì dá láre ni ó dá lọ́lá.


Ìdí rẹ̀ ni pé kí ibukun Abrahamu lè kan àwọn tí kì í ṣe Juu nípasẹ̀ Kristi Jesu, kí á lè gba ìlérí Ẹ̀mí nípa igbagbọ.


Ẹ máa ṣoore fún ara yín, ẹ ní ojú àánú; kí ẹ sì máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti dáríjì yín nípasẹ̀ Kristi.


Kí ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni kò fi burúkú gbẹ̀san burúkú lára ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn nígbà gbogbo kí ẹ máa lépa nǹkan rere láàrin ara yín ati láàrin gbogbo eniyan.


Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà.


Ó ní, “Ní ti ibukun, n óo bukun ọ. Ní ti kí eniyan pọ̀, n óo sọ ọ́ di pupọ.”


Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀.


Kí OLUWA má ṣe jẹ́ kí n pa ẹni àmì òróró rẹ̀. Nítorí náà, jẹ́ kí á mú ọ̀kọ̀ rẹ̀ ati ìgò omi rẹ̀ kí á sì máa lọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan