Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:7 - Yoruba Bible

7 Kí ẹ̀yin ọkọ náà máa fi ọgbọ́n bá àwọn aya yín gbé. Ẹ máa bu ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí kò lágbára to yín. Ẹ ranti pé wọ́n jẹ́ alábàápín ẹ̀bùn ìyè pẹlu yín. Tí ẹ bá ń ṣe èyí, kò ní sí ìdènà ninu adura yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Bẹ̃ gẹgẹ ẹnyin ọkọ, ẹ mã fi oye bá awọn aya nyin gbé, ẹ mã fi ọla fun aya, bi ohun èlo ti kò lagbara, ati pẹlu bi ajumọ-jogun ore-ọfẹ ìye; ki adura nyin ki o má bã ni ìdena.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:7
20 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”


“Mo tún sọ fun yín pé bí ẹni meji ninu yín bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé nípa ohunkohun tí wọn bá bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún wọn láti ọ̀dọ̀ Baba mi tí ń bẹ lọ́run.


Ọkọ gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu iyawo rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni iyawo náà gbọdọ̀ máa ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu ọkọ rẹ̀.


Àṣírí yìí ni pé àwọn tí kì í ṣe Juu ní anfaani láti pín ninu ogún pẹlu àwọn Juu, ara kan náà sì ni wọ́n pẹlu àwọn tí wọ́n jọ ní ìlérí ninu Kristi Jesu nípasẹ̀ ìyìn rere rẹ̀.


Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà.


Àkàwé yìí ba yín mu. Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níláti fẹ́ràn aya rẹ̀ bí òun tìkararẹ̀. Aya sì níláti bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.


Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun.


Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín. Ẹ má ṣe kanra mọ́ wọn.


Kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín mọ ọ̀nà láti máa bá aya rẹ̀ gbé pọ̀ pẹlu ìwà mímọ́ ati iyì,


Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.


Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.


Bákan náà ni kí ẹ̀yin aya máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọkọ yín. Ìdí rẹ̀ ni pé bí a bá rí ninu àwọn ọkọ tí kò jẹ́ onigbagbọ, wọ́n lè yipada nípa ìwà ẹ̀yin aya wọn láìjẹ́ pé ẹ bá wọn sọ gbolohun kan nípa ẹ̀sìn igbagbọ,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan