Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:4 - Yoruba Bible

4 Ṣugbọn kí ẹwà yín jẹ́ ti ọkàn tí kò hàn sóde, ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Èyí ni ẹwà tí kò lè ṣá, èyí tí ó ṣe iyebíye lójú Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ṣugbọn ki o jẹ ti ẹniti o farasin li ọkàn, ninu ọ̀ṣọ́ aidibajẹ ti ẹmí irẹlẹ ati ẹmí tutù, eyiti iṣe iyebiye niwaju Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:4
40 Iomraidhean Croise  

Kàkà bẹ́ẹ̀, mo fi ara mi lọ́kàn balẹ̀, mo dákẹ́ jẹ́ẹ́, bí ọmọ ọwọ́ tíí dákẹ́ jẹ́ẹ́ láyà ìyá rẹ̀. Ọkàn mi balẹ̀ bíi ti ọmọ ọwọ́ tó dákẹ́ jẹ́ẹ́.


OLUWA ní ń gbé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ró, òun ni ó sì ń sọ àwọn eniyan burúkú di ilẹ̀ẹ́lẹ̀.


Nítorí pé inú OLUWA dùn sí àwọn eniyan rẹ̀, a sì máa fi ìṣẹ́gun dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé.


A máa tọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ láti ṣe ohun tí ó tọ́, a sì máa kọ́ wọn ní ìlànà rẹ̀.


Yóo máa wá ojurere rẹ, pẹlu oríṣìíríṣìí ọrọ̀. Ọmọ ọbabinrin fi aṣọ wúrà ṣọ̀ṣọ́ jìngbìnnì ninu yàrá rẹ̀,


O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.


Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.


Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA. Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli


Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.


Ẹ̀mí OLUWA, Ọlọrun tí bà lé mi, nítorí ó ti fi àmì òróró yàn mí, láti mú ìròyìn ayọ̀ wá fún àwọn tí a ni lára. Ó rán mi pé kí n máa tu àwọn tí ó ní ìbànújẹ́ ninu, kí n máa kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn tí ó wà ní ìgbèkùn, kí n sì máa ṣí ìlẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n sílẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n.


Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya.


Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onírẹ̀lẹ̀ ati ọlọ́kàn tútù ni mí, ọkàn yín yóo sì balẹ̀.


“Ẹ sọ fún ọdọmọbinrin, Sioni, pé, Wo ọba rẹ tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ; pẹlu ìrẹ̀lẹ̀, ó gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹranko tí à ń lò láti rẹrù.”


Ìwọ afọ́jú Farisi! Kọ́kọ́ fọ inú ife ná, òde rẹ̀ náà yóo sì mọ́.


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé.


Ẹ̀yin aṣiwèrè wọnyi! Mo ṣebí ẹni tí ó dá òde, òun náà ni ó dá inú.


Ó wá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń dá ara yín láre lójú eniyan, ṣugbọn Ọlọrun mọ ọkàn yín. Ohun tí eniyan ń gbé gẹ̀gẹ̀, ohun ẹ̀gbin ni lójú Ọlọrun.


Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò.


Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan.


Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.


Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin.


Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín.


Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ.


ìwà pẹ̀lẹ́, ìsẹ́ra-ẹni. Kò sí òfin kan tí ó lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.


Kí ẹ máa hùwà pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ọkàn tútù, kí ẹ sì máa mú sùúrù. Kí ẹ máa fi ìfẹ́ bá ara yín lò nípa ìfaradà.


Nítorí náà, ẹ gbé àánú wọ̀ bí ẹ̀wù, ati inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù, bí ó ti yẹ àwọn ẹni tí Ọlọrun yàn, tí wọ́n sì jẹ́ eniyan Ọlọrun ati àyànfẹ́ rẹ̀.


Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun.


Ẹ gbìyànjú láti fi ọkàn yín balẹ̀. Ẹ má máa yọjú sí nǹkan oní-ǹkan. Ẹ tẹpá mọ́ṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín.


A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.


fún àwọn ọba, ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ipò gíga, pé kí á máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí á máa gbé ìgbé-ayé bí olùfọkànsìn ati bí ọmọlúwàbí.


Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí, bóyá Ọlọrun lè fún wọn ní ọkàn ìrònúpìwàdà, kí wọ́n lè ní ìmọ̀ òtítọ́,


Kí wọn má sọ ìsọkúsọ sí ẹnikẹ́ni. Kí wọn kórìíra ìjà. Kí wọn ní ìfaradà. Kí wọ́n máa fi ìrẹ̀lẹ̀ bá gbogbo eniyan lò.


Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là.


A ti tún yín bí! Kì í ṣe èso tí ó lè bàjẹ́ ni a fi tún yín bí bíkòṣe èso tí kò lè bàjẹ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó wà láàyè, tí ó sì wà títí.


Ṣugbọn ẹ fi ààyè fún Kristi ninu ọkàn yín bí Oluwa. Ẹ múra nígbà gbogbo láti dáhùn bí ẹnikẹ́ni bá bi yín ní ìbéèrè nípa ìrètí tí ẹ ní.


Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan