Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 3:3 - Yoruba Bible

3 Ẹwà yín kò gbọdọ̀ jẹ́ ti òde ara nìkan bíi ti irun-dídì, ati nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà tí ẹ kó sára ati aṣọ-ìgbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ọṣọ́ ẹniti ki o má jẹ ọṣọ́ ode, ti irun didì, ati ti wura lilo, tabi ti aṣọ wiwọ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 3:3
22 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí àwọn ràkúnmí rẹ̀ mu omi tán, tí gbogbo wọn yó, ọkunrin yìí fún un ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ìdajì ṣekeli, ati ẹ̀gbà ọwọ́ meji tí a fi wúrà ṣe tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ṣekeli wúrà mẹ́wàá.


Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.


Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu.


Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè.


Ní ọjọ́ kẹta, Ẹsita wọ aṣọ oyè rẹ̀, ó dúró ní àgbàlá ààfin ọba, ó kọjú sí gbọ̀ngàn ọba. Ọba jókòó lórí ìtẹ́ ninu gbọ̀ngàn rẹ̀, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà.


Àwọn ọmọ ọba wà lára àwọn obinrin inú àgbàlá rẹ, ayaba dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ó fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀ṣọ́ sára.


olukuluku obinrin yóo lọ sí ọ̀dọ̀ aládùúgbò rẹ̀ tí ó jẹ́ ará Ijipti ati àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóo tọrọ aṣọ ati ohun ọ̀ṣọ́ wúrà ati ti fadaka, ẹ óo sì fi wọ àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo sì ṣe gba gbogbo ìṣúra àwọn ará Ijipti lọ́wọ́ wọn.”


Aaroni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gba gbogbo yẹtí wúrà etí àwọn aya yín jọ, ati ti àwọn ọmọkunrin yín, ati ti àwọn ọmọbinrin yín, kí ẹ sì kó wọn wá.”


Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá.


Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA.


Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.


Jí, Sioni, jí! Gbé agbára rẹ wọ̀ bí aṣọ, gbé ẹwà rẹ wọ̀ bí ẹ̀wù, ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́; nítorí àwọn aláìkọlà ati aláìmọ́, kò ní wọ inú rẹ mọ́.


N óo máa yọ̀ ninu OLUWA, ọkàn mi yóo kún fún ayọ̀ sí Ọlọrun mi. Nítorí ó ti fi ìgbàlà wọ̀ mí bí ẹ̀wù, ó sì ti fi òdodo bòmí lára bí aṣọ; bí ọkọ iyawo tí ó ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, ati bí iyawo tí ó ṣe ọ̀ṣọ́ jìngbìnnì.


Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀? Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀? Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́.


Ìwọ tí o ti di ahoro, kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò? Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára? Tí o tọ́ ojú? Tí o tọ́ ètè? Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe, àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí, ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá.


“Wọ́n tilẹ̀ tún ranṣẹ lọ pe àwọn ọkunrin wá láti òkèèrè, oníṣẹ́ ni wọ́n gbé dìde kí ó lọ pè wọ́n wá; àwọn náà sì wá. Nígbà tí wọ́n dé, ẹ wẹ̀, ẹ kun àtíkè, ẹ tọ́ ojú, ẹ sì ṣe ara yín lọ́ṣọ̀ọ́.


Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.


nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà mímọ́ ati ìwà ọmọlúwàbí yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan