Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:9 - Yoruba Bible

9 Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ṣugbọn ẹnyin ni iran ti a yàn, olu-alufa, orilẹ-ède mimọ́, enia ọ̀tọ; ki ẹnyin ki o le fi ọla nla ẹniti o pè nyin jade kuro ninu òkunkun sinu imọlẹ iyanu rẹ̀ hàn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, Ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:9
50 Iomraidhean Croise  

Kí n lè rí ire àwọn àyànfẹ́ rẹ kí n lè ní ìpín ninu ayọ̀ àwọn eniyan rẹ, kí n sì lè máa ṣògo pẹlu àwọn tí ó jẹ́ eniyan ìní rẹ.


OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa. Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà, títí dé ibi ìwo pẹpẹ.


Nítorí pé OLUWA ti yan Jakọbu fún ara rẹ̀, ó ti yan Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.


Ìran tí ń bọ̀ yóo máa sìn ín; àwọn eniyan yóo máa sọ̀rọ̀ OLUWA fún àwọn ìran tí ń bọ̀.


Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn, àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀!


Bí mo bá ní, “N óo sọ̀rọ̀ báyìí,” n óo kó àwọn ọmọ rẹ ṣìnà.


Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè, kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé.


“Ìwọ ní tìrẹ, Israẹli iranṣẹ mi, Jakọbu, ìwọ tí mo ti yàn, ọmọ bíbí inú Abrahamu, ọ̀rẹ́ mi.


“N óo darí àwọn afọ́jú, n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí, n óo tọ́ wọn sọ́nà, ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí. N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn, n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú. N óo ṣe àwọn nǹkan, n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.


OLUWA ní: “Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu iranṣẹ mi ẹ̀yin ọmọ Israẹli, àyànfẹ́ mi.


ṣugbọn a óo máa pe ẹ̀yin ní alufaa OLUWA, àwọn eniyan yóo sì máa sọ̀rọ̀ yín bí iranṣẹ Ọlọrun wa. Ẹ̀yin ni ẹ óo máa jẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ọrọ̀ wọn ni ẹ óo sì máa fi ṣògo.


A óo máa pè yín ní, “Eniyan mímọ́”, “Ẹni-Ìràpadà-OLUWA”. Wọn óo máa pè yín ní, “Àwọn-tí-a-wá-ní-àwárí”; wọn óo sì máa pe Jerusalẹmu ní, “Ìlú tí a kò patì”.


N óo mú ninu wọn, n óo fi ṣe alufaa ati ọmọ Lefi.


Àwọn tí ń rìn ninu òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ sì ti tàn sí àwọn tí ń gbé ninu òkùnkùn biribiri.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn, wọn yóo jẹ́ ohun ìní mi pataki. N óo ṣàánú fún wọn bí baba tií ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.


Àwọn eniyan tí ó jókòó ní òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ìmọ́lẹ̀ mọ́ sórí àwọn tí ó jókòó ní ilẹ̀ tí òjìji ikú wà.”


Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.


láti tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn tí ó wà ní òkùnkùn ati àwọn tí ó jókòó níbi òjìji ikú, láti fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà alaafia.”


Nítorí tiwọn ni mo ṣe ya ara mi sí mímọ́, kí àwọn fúnra wọn lè di mímọ́ ninu òtítọ́.


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’


Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?”


Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu;


Bí ẹnikẹ́ni bá ba Tẹmpili Ọlọrun jẹ́. Ọlọrun yóo pa òun náà run. Nítorí mímọ́ ni Tẹmpili Ọlọrun, ẹ̀yin náà sì ni Tẹmpili Ọlọrun.


Ẹ̀mí Mímọ́ yìí jẹ́ onídùúró ogún tí a óo gbà nígbà tí Ọlọrun bá dá àwọn eniyan rẹ̀ nídè, kí á lè yin Ọlọrun lógo.


kí á lè mọyì ẹ̀bùn rẹ̀ tí ó lógo tí ó fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ Kristi àyànfẹ́ rẹ̀.


Kí ògo yìí wà fún un ninu ìjọ ati ninu Kristi Jesu láti ìrandíran títí laelae. Amin.


sibẹsibẹ Ọlọrun fẹ́ràn àwọn baba yín tóbẹ́ẹ̀ tí ó yan ẹ̀yin arọmọdọmọ wọn, ó yàn yín láàrin gbogbo eniyan tí ó wà láyé.


Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.


Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.


Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí.


Nítorí pé, ẹni mímọ́ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA Ọlọrun yín ti yàn yín, láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní gbogbo ayé, pé kí ẹ jẹ́ ohun ìní fún òun.


Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi tíí ṣe èrè ìpè láti òkè wá: ìpè Ọlọrun ninu Kristi Jesu.


Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀.


tí ó gbà wá là, tí ó pè wá láti ya ìgbé-ayé wa sọ́tọ̀. Kì í ṣe pé ìwà wa ni ó dára tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pè wá. Ṣugbọn ó pè wá gẹ́gẹ́ bí ètò tí òun fúnrarẹ̀ ti ṣe, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó fi fún wa nípasẹ̀ Kristi Jesu láti ayérayé.


ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.


Ẹ̀yin ni a yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọrun Baba fún ìwà mímọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kí ẹ lè máa gbọ́ ti Jesu Kristi, kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì lè wẹ̀ yín mọ́. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia kí ó pọ̀ fun yín.


Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi.


Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.


Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin.


Àwọn eniyan Ọlọrun tí ó bá ní ìpín ninu ajinde kinni ṣe oríire. Ikú keji kò ní ní àṣẹ lórí wọn. Wọn óo jẹ́ alufaa Ọlọrun ati ti Kristi, wọn óo sì jọba pẹlu rẹ̀ fún ẹgbẹrun ọdún.


O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa. Wọn yóo máa jọba ní ayé.”


OLUWA kò ní ta eniyan rẹ̀ nù, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀, nítorí pé ó wù ú láti ṣe yín ní eniyan rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan