Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 2:1 - Yoruba Bible

1 Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NITORINA ẹ fi arankàn gbogbo lelẹ li apakan, ati ẹ̀tan gbogbo, ati agabagebe, ati ilara, ati sisọ ọ̀rọ buburu gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 2:1
50 Iomraidhean Croise  

“Àwọn tí kò mọ Ọlọrun fẹ́ràn ibinu, wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́, nígbà tí ó bá fi wọ́n sinu ìdè.


Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí OLUWA kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn, tí ẹ̀tàn kò sì sí ninu ọkàn rẹ̀.


Ẹ ṣọ́ ẹnu yín, ẹ má sọ̀rọ̀ burúkú, ẹ má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu yín jáde.


Má gbé ara rẹ lọ́kàn gbóná nítorí àwọn eniyan burúkú; má sì jowú àwọn aṣebi;


Nítorí mò ń ṣe ìlara àwọn onigbeeraga nígbà tí mo rí ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.


Ìbàlẹ̀ ọkàn a máa mú kí ara dá ṣáṣá, ṣugbọn ìlara a máa dá egbò sinu eegun.


Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi, má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́,


Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi, má sì ṣe jowú eniyan burúkú,


Má ṣe ìlara ẹni ibi má sì ṣe tẹ̀ sí èyíkéyìí ninu àwọn ọ̀nà rẹ̀.


Ní ọjọ́ náà, àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù, ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ. Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.


Àwọn oriṣa tí ẹ yọ́ fadaka bò, ati àwọn ère tí ẹ yọ́ wúrà bò yóo di nǹkan èérí lójú yín. Ẹ óo kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bí nǹkan aláìmọ́. Ẹ óo sì wí fún wọn pé, “Ẹ pòórá!”


Ẹ̀yin alaiṣootọ! Òtítọ́ ni Aisaya ti sọtẹ́lẹ̀ nípa yín nígbà tí ó wí pé,


Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ̀yin náà rí lóde, lójú àwọn eniyan ẹ dàbí ẹni rere, ṣugbọn ẹ kún fún àṣehàn ati ìwà burúkú.


Ọ̀gá rẹ̀ yóo wá nà án, yóo fi í sí ààrin àwọn alaiṣootọ. Níbẹ̀ ni yóo máa gbé sunkún tí yóo sì máa payínkeke.


Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.


Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka kan wá fún mi kí n rí i.”


Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”


Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.


Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.


Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”


Wọ́n wá kún fún oríṣìíríṣìí ìwà burúkú: ojúkòkòrò, ìkà, owú jíjẹ, ìpànìyàn, ìrúkèrúdò, ẹ̀tàn, inú burúkú. Olófòófó ni wọ́n,


Ará, ẹ má máa ṣe bí ọmọde ninu èrò yín. Ó yẹ kí ẹ dàbí ọmọde tí kò mọ ibi, ṣugbọn kí ẹ jẹ́ àgbàlagbà ninu èrò yín.


Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.


Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò.


Ẹ níláti mú gbogbo inú burúkú, ìrúnú, ibinu, ariwo ati ìsọkúsọ kúrò láàrin yín ati gbogbo nǹkan burúkú.


Nítorí pé ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ohun ìṣìnà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ohun èérí tabi ti ìtànjẹ.


Bákan náà ni àwọn obinrin níláti jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́; kí wọn má jẹ́ abanijẹ́. Kí wọn jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, kí wọn jẹ́ ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu ohun gbogbo.


Bákan náà, àwọn àgbà obinrin níláti jẹ́ ẹni tí gbogbo ìgbé-ayé wọn bá ti ìsìn Ọlọrun mu. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ onísọkúsọ tabi ẹrú ọtí. Wọ́n níláti máa kọ́ni ní ohun rere.


Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.


Nítorí náà, ẹ mú gbogbo ìwà èérí ati gbogbo ìwàkiwà à-ń-wá-ipò-aṣaaju kúrò, kí á lè wà ní ipò kinni. Ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ gba ọ̀rọ̀ tí a gbìn sinu yín, tí ó lè gba ọkàn yín là.


Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́.


Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí.


Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?”


Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe bá ara yín wí, kí á má baà da yín lẹ́jọ́. Onídàájọ́ ti dúró lẹ́nu ọ̀nà.


Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun.


Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí.


Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹni tí ó bá fẹ́ ìgbé-ayé tí ó wù ú, tí ó fẹ́ rí ọjọ́ tí ó dára, ó níláti kó ara rẹ̀ ni ìjánu pẹlu ọ̀rọ̀ burúkú sísọ, kí ó má fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.


Má tún máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀dá mọ́, ṣugbọn máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun ninu gbogbo ìgbé-ayé rẹ tí ó kù.


Nisinsinyii ó jẹ́ ohun ìjọjú fún àwọn ẹlẹgbẹ́ yín àtijọ́, nígbà tí ẹ kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayé ìjẹkújẹ mọ́, wọn óo wá máa fi yín ṣe ẹlẹ́yà.


Ọ̀rọ̀ èké kankan kò sí ní ẹnu wọn. Kò sí àléébù ninu ìgbé-ayé wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan