Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:8 - Yoruba Bible

8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i, sibẹ ẹ fẹ́ràn rẹ̀. Ẹ kò rí i sójú nisinsinyii, sibẹ ẹ gbà á gbọ́, ẹ sì ń yọ ayọ̀ tí ẹnu kò lè sọ, ayọ̀ tí ó lógo,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ẹniti ẹnyin fẹ lairi, ẹniti ẹnyin gbagbọ, bi o tilẹ ṣepe ẹ kò ri i nisisiyi, ẹnyin si nyọ ayọ̀ ti a kò le fi ẹnu sọ, ti o si kun fun ogo:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:8
37 Iomraidhean Croise  

Sọ fún mi, ìwọ ẹni tí ọkàn mi fẹ́: níbo ni ò ó máa ń da àwọn ẹran rẹ lọ jẹko? Níbo ni wọ́n ti ń sinmi, nígbà tí oòrùn bá mú? Kí n má baà máa wá ọ kiri, láàrin agbo ẹran àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ?


Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ dùn, àfi bí oyin, ó wuni lọpọlọpọ. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, òun ni olùfẹ́ mi, òun sì ni ọ̀rẹ́ mi,


Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin? Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ? Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?


“Ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba tabi ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.


“Bí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ óo pa òfin mi mọ́.


“Ẹni tí ó bá gba òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ó fẹ́ràn mi. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn mi, Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi náà yóo fẹ́ràn rẹ̀, n óo sì fi ara mi hàn án.”


Ẹni tí kò bá fẹ́ràn mi kò ní tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Ọ̀rọ̀ tí ẹ ń gbọ́ kì í ṣe tèmi, ti Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.


Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín.


Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”


Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.


Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.


Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni.


Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.


Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ràn Oluwa wa, ẹni ègún ni! Marana ta–Oluwa wa, máa bọ̀!


Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.


Kì í ṣe àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí ni a tẹjúmọ́, bíkòṣe àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí. Nítorí àwọn nǹkan tí yóo wà fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn nǹkan tí a lè fi ojú rí. Àwọn nǹkan tí a kò lè fi ojú rí ni yóo wà títí laelae.


Nítorí igbagbọ ni a fi ń gbé ìgbé-ayé wa, kì í ṣe ohun tí à ń fi ojú rí.


Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà.


Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,


Nítorí ọ̀ràn pé a kọlà tabi a kò kọlà kò jẹ́ nǹkankan fún àwọn tí ó wà ninu Kristi Jesu. Ohun tí ó ṣe kókó ni igbagbọ tí ó ń ṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.


kí ẹ lè mọ bí ìfẹ́ Kristi ti tayọ ìmọ̀ ẹ̀dá tó, kí ẹ sì lè kún fún gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọrun.


Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin.


Èyí dá mi lójú, nítorí náà mo mọ̀ pé n óo wà láàyè. Bí mo bá wà ní ọ̀dọ̀ gbogbo yín, yóo mú ìlọsíwájú ati ayọ̀ ninu igbagbọ wá fun yín.


Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,


Ẹ máa yọ̀ ninu Oluwa nígbà gbogbo. Mo tún wí: ẹ máa yọ̀.


Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.


Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn.


Ẹ máa yọ̀ nítorí èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé fún àkókò díẹ̀, ẹ níláti ní ìdààmú nípa oríṣìíríṣìí ìdánwò.


Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki igun ilé.”


Nígbà tí Olú olùṣọ́-aguntan bá dé, ẹ óo gba adé ògo tí kì í ṣá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan