1 Peteru 1:3 - Yoruba Bible3 A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa wa, tí ó fi ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀ tún wa bí sí ìrètí tí ó wà láàyè nípa ajinde Jesu Kristi kúrò ninu òkú. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú, Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, Faic an caibideil |
Ó bá gbadura sí OLUWA, ó ní: “OLUWA, ṣebí ohun tí mo sọ láti ìbẹ̀rẹ̀ nìyí, nígbà tí mo wà ní orílẹ̀-èdè mi? Nítorí náà ni mo ṣe sa gbogbo ipá mi láti sálọ sí Taṣiṣi; nítorí mo mọ̀ pé Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ ati aláàánú ni ọ́, o ní sùúrù, o kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ò sì máa yí ibi tí o bá ti pinnu láti ṣe pada.