Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:12 - Yoruba Bible

12 Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:12
56 Iomraidhean Croise  

Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà.


Ẹ fetí sí ìbáwí mi, n óo ṣí ọkàn mi payá fun yín, n óo sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi ye yín.


Bẹ́ẹ̀ ni nǹkan yóo rí, títí ẹ̀mí óo fi bà lé wa láti òkè ọ̀run wá títí aṣálẹ̀ yóo fi di ọgbà eléso, tí ọgbà eléso yóo sì fi di igbó.


Ta ló lè gba ìyìn tí a rò gbọ́? Ta ni a ti fi agbára OLUWA hàn?


Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli.


“Ṣugbọn, ìwọ Daniẹli, máa ṣe tìrẹ lọ títí dé òpin. O óo lọ sí ibi ìsinmi, ṣugbọn lọ́jọ́ ìkẹyìn, o óo dìde nílẹ̀ o óo sì gba ìpín tìrẹ tí a ti fi sílẹ̀ fún ọ.”


Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn.


Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo.


Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.


Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”


Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”


“Ọlọrun ti fi àṣẹ sí i pé, lẹ́yìn aadọrin ọdún lọ́nà meje ni òun óo tó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan rẹ ati ti ìlú mímọ́ rẹ jì wọ́n, tí òun óo ṣe ètùtù fún ìwà burúkú wọn, tí òun óo mú òdodo ainipẹkun ṣẹ, tí òun óo fi èdìdì di ìran ati àsọtẹ́lẹ̀ náà, tí òun óo sì fi òróró ya Ilé Mímọ́ Jùlọ rẹ̀ sọ́tọ̀.


“Lẹ́yìn náà, nígbà tí ó bá yá, n óo tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo eniyan, àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin yín yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, àwọn àgbààgbà yín yóo máa lá àlá, àwọn ọdọmọkunrin yín yóo sì máa ríran.


“Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.


“N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.


Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.


Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.


Ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí gbogbo ayé, kí ẹ máa waasu ìyìn rere fún gbogbo ẹ̀dá.


Mo sọ fun yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn angẹli Ọlọrun yóo máa yọ̀ nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronupiwada.”


Ẹ̀mí Mímọ́ ti fihàn án pé kò ní tíì kú tí yóo fi rí Mesaya tí Oluwa ti ṣe ìlérí.


Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá ń lọ láti abúlé dé abúlé, wọ́n ń waasu ìyìn rere, wọ́n sì ń ṣe ìwòsàn níbi gbogbo.


“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.


Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.


Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀.


Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí.


Bí wọ́n ti ń gbadura, ibi tí wọ́n péjọ sí mì tìtì, gbogbo wọn bá kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n bá ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ wá fún Peteru ní agbára lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ó bá sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìjòyè láàrin àwọn eniyan ati ẹyin àgbààgbà,


Lẹ́yìn tí Peteru ati Johanu ti jẹ́rìí tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Oluwa tán, wọ́n pada sí Jerusalẹmu. Wọ́n ń waasu ìyìn rere ní ọpọlọpọ àwọn abúlé ilẹ̀ Samaria bí wọ́n ti ń pada lọ.


Ìdí rẹ̀ nìyí tí mo ṣe ń dàníyàn láti waasu ìyìn rere fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Romu náà.


Ninu ìyìn rere yìí ni a ti ń fi ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dá eniyan láre hàn wá: nípa igbagbọ ni, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí igbagbọ ni ẹni tí a bá dá láre yóo fi yè.”


Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!”


pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun.


Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.


À ń ṣiṣẹ́ pẹlu ọkàn kan; pẹlu ọgbọ́n ati sùúrù, pẹlu inú rere ati ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́, pẹlu ìfẹ́ tí kò lẹ́tàn.


Kì í ṣe ọwọ́ eniyan ni mo ti gbà á, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe eniyan ni ó kọ́ mi. Jesu Kristi ni ó fihàn mí.


láti fi Ọmọ rẹ̀ hàn ninu mi, kí n lè máa waasu ìyìn rere rẹ̀ láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Nígbà tí ó pè mí, n kò bá ẹnikẹ́ni gbèrò,


kí ó lè sọ ọ́ di mímọ̀ ní àkókò yìí láti ọ̀dọ̀ ìjọ, kí ó sì lè fihan àwọn alágbára ati àwọn aláṣẹ tí ó wà ninu àwọn ọ̀run bí ọgbọ́n Ọlọrun ti pọ̀ tó ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà.


Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.


Kò sí ẹni tí kò mọ̀ pé àṣírí ẹ̀sìn wa jinlẹ̀ pupọ: Ẹni tí ó farahàn ninu ẹran-ara, tí a dá láre ninu ẹ̀mí, tí àwọn angẹli fi ojú rí, tí à ń waasu rẹ̀ láàrin àwọn alaigbagbọ, tí a gbàgbọ́ ninu ayé, tí a gbé lọ sinu ògo.


Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé.


Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.


Nítorí àwa náà ti gbọ́ ìyìn rere bí àwọn tọ̀hún ti gbọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ̀ tí àwọn gbọ́ kò ṣe wọ́n ní anfaani, nítorí wọn kò ní igbagbọ ninu ohun tí wọ́n gbọ́.


ṣugbọn ọ̀rọ̀ Oluwa yóo wà títí lae.” Òun ni ọ̀rọ̀ tí à ń waasu rẹ̀ fun yín.


Nítorí rẹ̀ ni a ṣe waasu ìyìn rere fún àwọn òkú, pé bí wọ́n bá tilẹ̀ gba ìdájọ́ bí gbogbo eniyan ti níláti gbà ninu ara, sibẹ wọn óo wà láàyè ninu ẹ̀mí nípa ti Ọlọrun.


Bí mo tí ń wò, mo gbọ́ ohùn ọpọlọpọ àwọn angẹli tí wọ́n yí ìtẹ́ náà ká ati àwọn ẹ̀dá alààyè ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun. Àwọn angẹli náà pọ̀ pupọ: ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun àìmọye.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan