Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Peteru 1:1 - Yoruba Bible

1 Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 PETERU, Aposteli Jesu Kristi, si awọn ayanfẹ ti nṣe atipo ti nwọn tuka kiri si Pontu, Galatia, Kappadokia, Asia, ati Bitinia,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Peteru, aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Peteru 1:1
34 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ.


O ti ṣe wá bí aguntan lọ́wọ́ alápatà, o sì ti fọ́n wa káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.


“ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé.


N óo fọ́n yín káàkiri ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, idà ni wọn yóo máa fi pa yín ní ìpakúpa, ilẹ̀ yín ati àwọn ìlú yín yóo di ahoro.


Orúkọ àwọn aposteli mejila náà nìwọ̀nyí: Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀; lẹ́yìn náà Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀.


Bí Ọlọrun kò bá dín àwọn ọjọ́ náà kù ni, ẹ̀dá kankan kì bá tí là. Ṣugbọn nítorí àwọn àyànfẹ́, Ọlọrun yóo dín àwọn ọjọ́ náà kù.


Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.


Ǹjẹ́ Ọlọrun kò ní ṣe ẹ̀tọ́ nípa àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọn ń pè é lọ́sàn-án ati lóru? Ǹjẹ́ kò ní tètè dá wọn lóhùn?


Kì í wá ṣe fún orílẹ̀-èdè wọn nìkan, ṣugbọn kí àwọn ọmọ Ọlọrun tí ó fọ́nká lè papọ̀ di ọ̀kan.


Àwọn Juu bẹ̀rẹ̀ sí sọ láàrin ara wọn pé, “Níbo ni ọkunrin yìí yóo lọ tí àwa kò fi ní rí i? Àbí ó ha fẹ́ lọ sí ààrin àwọn ará wa tí ó fọ́nká sí ààrin àwọn Giriki ni?


Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn.


Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le.


Báyìí ló ṣe fún ọdún meji, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń gbé Esia: ati Juu ati Giriki, ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa.


Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn.


Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà.


Gbogbo ìjọ tí ó wà ní Esia kí yín. Akuila ati Pirisila ati ìjọ tí ó wà ní ilé wọn ki yín pupọ ninu Oluwa.


Ẹ̀yin ará, a kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa ìpọ́njú tí ó tayọ agbára wa tí a ní ní Esia, Ìdààmú náà wọ̀ wá lọ́rùn tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀mí wa fi fẹ́rẹ̀ bọ́.


Èmi ati gbogbo arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ni à ń kọ ìwé yìí sí àwọn ìjọ Galatia.


Nígbà náà ẹ wà ní ipò ẹni tí kò mọ Kristi. Ẹ jẹ́ àjèjì sí àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ Israẹli. Àwọn majẹmu tí ó ní ìlérí Ọlọrun ninu sì tún ṣe àjèjì si yín. Ẹ wà ninu ayé láìní ìrètí ati láìní Ọlọrun.


Nítorí náà, ẹ kì í tún ṣe àlejò ní ìlú àjèjì mọ́, ṣugbọn ẹ jẹ́ ọmọ-ìbílẹ̀ pẹlu àwọn onigbagbọ, ẹ sì di mọ̀lẹ́bí ninu agbo-ilé Ọlọrun.


OLUWA yóo fọ́n yín káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa káàkiri, ati èyí tí wọ́n fi igi gbẹ́, ati èyí tí wọn fi òkúta ṣe, tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí.


Ǹ bá wí pé kí n fọ́n wọn káàkiri, kí ẹnikẹ́ni má tilẹ̀ ranti wọn mọ́,


OLUWA yóo fọn yín káàkiri sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí wọn yóo sì ṣẹ́kù ninu yín kò ní tó nǹkan láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA yóo fọn yín ká sí.


O kò ní ṣàìmọ̀ pé gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè Esia ti sá kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó fi mọ́ Fugẹlọsi ati Hemogenesi.


Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé.


Èmi Jakọbu, iranṣẹ Ọlọrun, ati ti Oluwa wa, Jesu Kristi, ni ó ń kọ ìwé yìí sí àwọn ẹ̀yà mejila tí ó fọ́nká gbogbo ayé. Alaafia fun yín!


Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun.


Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.


ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan