Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:9 - Yoruba Bible

9 Ọ̀nà tí Ọlọrun fi fi ìfẹ́ tí ó ní sí wa hàn ni pé ó ti rán ààyò ọmọ rẹ̀ wá sáyé kí á lè ní ìgbàlà nípasẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nípa èyí ni a gbé fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú wa, nítorí tí Ọlọ́run rán ọmọ bíbí rẹ̀ nìkan ṣoṣo sì ayé, kí àwa lè yè nípasẹ̀ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:9
27 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun ní, “Mú Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo tí o fẹ́ràn, kí o lọ sí ilẹ̀ Moraya, kí o sì fi ọmọ náà rú ẹbọ sísun lórí ọ̀kan ninu àwọn òkè tí n óo júwe fún ọ.”


N óo kéde ohun tí OLUWA pa láṣẹ ní ti èmi ọba; Ó wí fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.


Ó wá ku ẹnìkan tíí ṣe àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Òun ni ó rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọn yóo bu ọlá fún ọmọ mi.’


“Ẹ̀mí Oluwa wà pẹlu mi nítorí ó ti fi òróró yàn mí láti waasu ìyìn rere fún àwọn talaka. Ó rán mi láti waasu ìtúsílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, ati láti mú kí àwọn afọ́jú ríran; láti jẹ́ kí àwọn tí a ni lára lọ ní alaafia,


Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.


A kò ní dá ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ lẹ́bi. Ṣugbọn a ti dá ẹni tí kò bá gbà á gbọ́ lẹ́bi ná, nítorí kò gba orúkọ Ọmọ bíbí Ọlọrun kanṣoṣo gbọ́.


kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.”


Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.”


Gẹ́gẹ́ bí Baba alààyè ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wà láàyè nítorí ti Baba. Ẹni tí ó bá jẹ ẹran ara mi, yóo yè nítorí tèmi.


Ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ wà pẹlu mi, kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan, nítorí mò ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.”


Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.


Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni.


Ọlọrun, tí kò dá Ọmọ rẹ̀ sí, ṣugbọn tí ó yọ̀ǹda rẹ̀ nítorí gbogbo wa, báwo ni kò ṣe ní fún wa ní ohun gbogbo pẹlu rẹ̀?


Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ?” Tabi tí ó sọ fún pé, “Èmi yóo jẹ́ baba fún un, òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?”


Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa náà fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará.


Ọ̀nà tí a fi mọ ìfẹ́ nìyí: kì í ṣe pé àwa ni a fẹ́ràn Ọlọrun ṣugbọn òun ni ó fẹ́ràn wa, tí ó rán ọmọ rẹ̀ wá sáyé láti jẹ́ ọ̀nà ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.


Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀.


Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan