Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:8 - Yoruba Bible

8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun nítorí ìfẹ́ ni Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọ́run: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọ́run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:8
14 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn ìwọ, OLUWA, ni Ọlọrun aláàánú ati olóore; o kì í tètè bínú, o sì kún fún ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́.


Nítorí pé olóore ni ọ́, OLUWA, o máa ń dárí jini; ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ sì pọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́.


Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ó dìgbà! Ẹ tún ọ̀nà yín ṣe. Ẹ gba ìkìlọ̀ wa. Ẹ ní ọkàn kan náà láàrin ara yín. Ẹ máa gbé pọ̀ ní alaafia. Ọlọrun ìfẹ́ ati alaafia yóo wà pẹlu yín.


Ṣugbọn nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ọlọrun tí ó ní àánú pupọ ní sí wa,


nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.


Iṣẹ́ tí ó fi rán wa, tí à ń jẹ́ fun yín nìyí: pé ìmọ́lẹ̀ ni Ọlọrun, kò sí òkùnkùn ninu rẹ̀ rárá.


Òpùrọ́ ni ẹni tí ó bá wí pé òun mọ̀ ọ́n, ṣugbọn tí kò bá máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, kò sí òtítọ́ ninu olúwarẹ̀.


Ẹni tí ó bá wí pé òun wà ninu ìmọ́lẹ̀, tí ó kórìíra arakunrin rẹ̀, wà ninu òkùnkùn sibẹ.


Ọ̀nà tí a fi lè mọ àwọn ọmọ Ọlọrun yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Èṣù nìyí: gbogbo ẹni tí kò bá ṣe iṣẹ́ òdodo tí kò sì fẹ́ràn arakunrin rẹ̀ kò wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Gbogbo ẹni tí ó bá ń gbé inú rẹ̀ kò ní máa dẹ́ṣẹ̀. Ẹni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀ kò ì tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n.


A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.


Olùfẹ́, ẹ jẹ́ kí á fẹ́ràn ẹnìkejì wa, nítorí ìfẹ́ ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti bí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìfẹ́, ó sì mọ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan