Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




1 Johanu 4:6 - Yoruba Bible

6 Ti Ọlọrun ni àwa; Ẹni tí ó bá mọ Ọlọrun ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í bá ṣe ti Ọlọrun kò ní gbọ́ tiwa. Ọ̀nà tí a fi mọ Ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí ìtànjẹ yàtọ̀ nìyí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




1 Johanu 4:6
33 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀mí náà dáhùn pé, ‘N óo lọ sọ gbogbo àwọn wolii Ahabu di wolii èké.’ OLUWA bá dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ ni kí o lọ tàn án jẹ, o óo sì ṣe àṣeyọrí, lọ ṣe bí o ti wí.’ ”


Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú; ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.


Ẹ lọ wádìí ninu ẹ̀kọ́ mímọ́ ati ẹ̀rí. Bí ẹnìkan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí, kò sí òye ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.


Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ.


“Wolii tí yóo máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ ati ẹ̀tàn ni àwọn eniyan wọnyi ń fẹ́, tí yóo sì máa waasu pé, ‘Ẹ óo ní ọpọlọpọ waini ati ọtí líle.’


Ṣugbọn ní tèmi, mo kún fún agbára, ati ẹ̀mí OLUWA, ati fún ìdájọ́ òdodo ati ipá, láti kéde ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, ati láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli fún wọn.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”


Mo tún ní àwọn aguntan mìíràn tí kò sí ninu agbo yìí. Mo níláti dà wọ́n wá. Wọn yóo gbọ́ ohùn mi. Wọn yóo wá di agbo kan lábẹ́ olùṣọ́-aguntan kan.


Àwọn aguntan mi a máa gbọ́ ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọn a sì máa tẹ̀lé mi.


Òun ni olùṣọ́nà ń ṣí ìlẹ̀kùn fún. Àwọn aguntan a máa gbọ́ ohùn rẹ̀, a sì máa pe àwọn aguntan rẹ̀ ní orúkọ, a máa kó wọn lọ jẹ.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán níṣẹ́, èmi ni ó gbà. Ẹni tí ó bá gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.”


Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.


“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.


Ṣugbọn nígbà tí Ẹ̀mí òtítọ́ tí mo wí bá dé, yóo tọ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo. Nítorí kò ní sọ ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀; gbogbo ohun tí ó bá gbọ́ ni yóo sọ. Yóo sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ fun yín.


Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”


Ó tún kí wọn pé, “Alaafia fún yín! Gẹ́gẹ́ bí baba ti rán mi níṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mo rán yín.”


Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.”


Ó wá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin, ní tiyín, ìsàlẹ̀ ni ẹ ti wá, ṣugbọn ní tèmi, òkè ọ̀run ni mo ti wá. Ti ayé yìí ni yín, èmi kì í ṣe ti ayé yìí.


Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀.


gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ọlọrun fún wọn ní iyè tí ó ra, ojú tí kò ríran, ati etí tí kò gbọ́ràn títí di òní olónìí.”


Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé wolii ni òun tabi pé òun ní agbára Ẹ̀mí, kí olúwarẹ̀ mọ̀ pé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa ni ohun tí mo kọ ranṣẹ si yín yìí.


Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́.


Nígbà náà ni yóo gbẹ̀san lára àwọn tí kò mọ Ọlọrun ati àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ ìyìn rere Oluwa wa Jesu.


Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá.


Ẹ ranti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ ati òfin Oluwa wa ati Olùgbàlà tí ẹ gbà lọ́wọ́ aposteli yín.


Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹni tí ó bá wí pé òun ní Ẹ̀mí Ọlọrun gbọ́. Ẹ kọ́kọ́ wádìí wọn láti mọ ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, nítorí ọpọlọpọ àwọn èké wolii ti wọ inú ayé.


Ẹ̀yin ọmọde, ti Ọlọrun nìyí, ẹ ti ṣẹgun ẹ̀mí alátakò Kristi nítorí pé ẹni tí ó wà ninu yín tóbi ju ẹni tí ó wà ninu ayé lọ.


Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun nítorí ìfẹ́ ni Ọlọrun.


A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.


Ṣugbọn ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, ẹ̀yin ẹ ranti ohun tí Oluwa wa Jesu Kristi ti ti ẹnu àwọn aposteli rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan